ITAN NIPA HUBERT OGUNDE (YORUBA)
Ohun un to yẹ ko mọ nipa Hubert Ogunde: # Ọjọ Kẹwaa, osu Keje, ọdun 1916, eyiun ọdun mejilelọgọrun (102) sẹyin ni Hubert Ogunde fi ori sọlẹ si ilu Ọ̀sọsà, nipinlẹ Ogun Jeremiah Deinbọ ati Eunice Owotusan Ogunde lo se ọkọ rẹ wa sile aye, Olusọagutan si ni baba rẹ. # Ọdọ baba iya rẹ to jẹ onifa, ni Hubert gbe fun igba kan, eyi to mu ko mọ nipa Ifa, Ogun atawọn orisa abalaye miran Ogunde sisẹ lẹyin to pari iwe mẹfa rẹ tan bii olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ọga akọrin ni sọọsi ati atẹduru # Ẹgbẹ Eegun Alarinjo lo fi bẹrẹ isẹ tiata, ko to dara pọ mọ isẹ ọlọpaa, o si de ipo Kọsitebu, ko to fẹyinti Oun lo kọkọ mu ere tiata wọ inu ẹgbẹ alarinjo, eyi to sọ di oludasilẹ ere tiata Lara awọn ere onise to se ni ‘Human Parasites’, eyi to fi n tako iwa sisare lati ra asọ ẹbi olowo iyebiye tii se ara ara Yoruba Ogunde jẹ ajijagbara fun iran Yoruba ati Naijiria, lati ipasẹ ọpọ ere to se fi tako awọn oyinbo amunisin. Lara ere naa ni ‘Bread and Bullet’ to se lọdun 1950. # Ogunde tun maa n lo e...